Feed Blog Circles Pages Dashboard
Add Post Add Memorial Create Circle Create Page
AD

Sponsor Odu Knowledge Pages

Landscape ad for all Odu routes.

Reach Audience
AD

Support Family Memorials

Dedicated landscape slot for memorial routes.

Create Memorial
I

Iwòrì Òwónrìn

Odu Ifa — Sacred Verse of the Oracle
Odu Ifa Yoruba Oracle 2 Languages Sacred Pattern
This Odu signifies the importance of adaptability and flexibility.
0 views Updated Mar 28, 2026 bode.ng/odu/iwori-owonrin
Read in: Yoruba Español English Português Français
Odu Ifa Sacred Divination Pattern

The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray

1
Ese Kinni
Ese Kinni

Ese — Yoruba Verse

Enu awo nije irinwon eku Enu awo nije irinwo eja Iwori oderin monjo lofa Asise nifi inu sele Nifi eyin sede Adifafun ajijobi Tii se omo bibi inu agboniregun Ebo ni won ni ko mon se O si gbebo nibe orubo Nje, ifa mon jeki ajijobi oku o Ipabi awo ki ku boroboro

Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)

Ki eleyi orubo nitori emi re, ki o mon fi eku ati eja bofa re pelu obi ki o si mon je esebi ti owa lori ifa

Ebo — Sacrifice (Yoruba)

Eku Eja Agbebo adie Obi Akuko adie meji Epo Eko
2
Ese Keji
Ese Keji

Ese — Yoruba Verse

Eeru awo kulo Elu awo ode obaramonje Opa aro nifidi pa ayinrin Adifafun olorubu okejo Okanla abori yebeyebe Igba ti nbe laarin ajogun omo araye Ebo ni won ni ko se O si gbebo nibe orubo Nje esunmi o eyin Afaimo ni sunni

Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)

Ki eleyi o mon pese fun awon agbalagba dada ki won le mon fi ori fi ese re jin

Ebo — Sacrifice (Yoruba)

Okete kan Akuko adie meji Eyele meji Epo Eko
3
Ese Keta
Ese Keta

Ese — Yoruba Verse

Enu awo nije irinwo eku Enu awo a je irinwo eja Iwori ni obewe kotorogun owonrin Adifafun orunmila Baba ngbogun rebi atoke doke Ebo ni won ni ko mon se Osi gbebo nibe orubo Kee pe Kee jinna Ogun tawo baja Ajasegun moni o

Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)

Ifa pe ogun kan nbe niwaju eleyi, korubo ko le ba a segun naa.

Ebo — Sacrifice (Yoruba)

oruko kan Obi Epo pupa Akuko meji Eko
4
Ese Kerin
Ese Kerin

Ese — Yoruba Verse

Opa aro nifidi payinrin Adifafun olofin Ti nsogbogbo arun Ti nara kaka alailadide Ebo ni won ni kose Osi gbebo nibe orubo Nje ogbo agborako Logbo alabahun Adagbarako ni ti igbin

Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)

Ki eleyii orubo ajinde ara ko mon rubo nitori aare

Ebo — Sacrifice (Yoruba)

Alabahun meji Igbin to pinu meji Epo Eko

Awure — Alchemist Formula

Yoruba

ISEGUN Ori alabahun kan tafi rubo Odidi atare kan totobi dada Aojo papo ao fi si gbere si aarin Lori koniye

Videos

Watch Iwòrì Òwónrìn teachings on our channel.

Explore Ifa

Iwòrì Òwónrìn is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).

Odus that share the same family or pairing include: Iwori Meji, Iwòrì Ogbè, Iwòrì Òyèkù, Iwòrì Òdì.

← Browse all 256 Odu Ifa  |  Seek Divination

Reflections & Testimonies

0 reflections shared

Be the first to share a reflection on Iwòrì Òwónrìn Odu.