I
This Odu emphasizes the importance of resilience and strength.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Iwori orinkan
Awo olore agbon
Adifafun olore agbon ti isale oja
Igbati nda saye re loun nikan
EBO ni won ni ko se
Osi gbebo nibe orubo
Nje iwori orikan
Atise rin lenikan
Taye fi yeni
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe eleyii nda se aye re ni ki orubo ki omon ba da se aye re mon.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu meji
Eyele meji
Akuko adie meji
Epo
Eko
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Moduro mori
Gbagede olofin
Mo bere mori
Yangidi odua
Babalawo ori
Adifafun ori
Ori ngbogun rode apere
Ebo ni won ni ko mon se
Nje ori loja lojara
Ori loja lode apere
Ori pele adudu mon da
Asakara mon leke
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ki eleyii orubo isegun pelu ibi ti o nlo ko ko lee baa ja ajasegun ki osi bio ori re daadaa
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Akuko adie meji
Pelu eye etu meji
Eyele naa meji
Epo
Eko
Obi
Oti
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Kogokogo lun agogo
Gbongbangbongan loun Ajija
Akifi ajija kede ilu
To ba re kete
Amadi ori agogo
Adifafun orunmila
Baba nlo lete ile aye do
Baba te ile aye do tan
Won ni ko mon losi ode orun
Ifa ni iro ni won pa
Ifa ni odo loni ki nbayin duro
Olo loni ki nmon le lo
Adosusu loni ki ewa duro timi laaye mi
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ki eleyii orubo dada lori nkan ti o fe se tori ti o ba se aseyori re tan aye ofe le ni aaye re kuro
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Oruko kan
Akuko meji
Eyele meji
Epo
Eko
Erunrun odo Erunrun olo
Pelu ewe adosusu
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Iwori orinkan
Awo ile agboniregun
Adifafun agboniregun
Igbati nsogbogbo gorun
Ti nira kaka alaile dide
Ebo ni won ni ko mose
O si gbebo nibe orubo
Kepe kejina ewa bawa
Laruse ogun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ki eleyii orubo ajinde ara ki osi rubo aare.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Akuko adie meji
Alabahun meji
Agbeboadie meji
Epo
Eko
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
AJE
Ewe adosusu
Ipepe ara odo ipepe ara olo
Ao gun papo ao po mon ose dudu
Ao mon fi ose na we eo mon se adure si
Explore Ifa
Iwòrì Òkánràn is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Iwori Meji, Iwòrì Ogbè, Iwòrì Òyèkù, Iwòrì Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Iwòrì Òkánràn Odu.
