Ò
This Odu highlights the need for patience and perseverance.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Petenbole Okirini Kisi
Ka susu oo le kafi disa eera
Adifafun ijimere
To oun aaya jo n sota
Ebo won ni won o se
Ijimere ni nkan ni be leyin ti n tubo
Ero ipo
Ero ofa
E ba ni laru segun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Keleyi orubo, ko si bo eegun pe eegun ni o ba eleyi segun ota Ore eleyi kan si ree ti won jo n sore, ko sora fun ore naa nitori ore naa yio gbabode fun ko si ma maa so oro enu re fun eleyi tan
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Epo
Eko
Agbado
Owo
A o fi eko olele, obi, ati oti bo eegun.
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Eti erin ni odojo poju erin
Adifafun orunmila
Baba n be laarin ota
Ebo won ni ose
O gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
Eba ni laru segun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Keleyii o rubo ko maa woran lenun loo lo yii nitori kire ajere ole to lowo, nitori ire aye eleyi ni orunmila wa lo toba wa nbo toba ba eleyi lode o ijo yio wo wipe eyin ewo eni toun torire nwa ajere kiri ki orunmila o maa baa wa ko irere fun elomi.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Epo
Eko
Agbado
Owo
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
A da taka agbigbo
Adifafun igunnugun
Omo agbelu jofe
Igba ti n tomi oju sogbere ire gbogbo
Ebo won ni ose
O gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E ba ni bola ba pere gede
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Keleyi orubo, eleyi n se wahala kotori Owo sugbon korubo ko ni se wahala mo koto ma n rowo sele aye omo orunmila ni eleyi ise awo leleyi yio se to yi o fi da
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Epo
Eko
Agbado
Etu
Owo
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Pepele ni ogbeleji
Adifafun orunmila
Baba o fowo adugbo se tie
Ebo won ni o se
O gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E ba ni ni moro ire.
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Keleyi orubo pe ire eleyi n be ni to si ire kire re ole te lomo keleyi osi ma n ma n se ahun ko si dimo oun ifa daada.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Epo
Eko
Agbado
Owo
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
ISEGUN
Ori ikun meji ori alegba meji ikoode meji odidi atare kan a o jopo oyin la o ma n fi laa laaro laaro
Explore Ifa
Òtúrá Ìrètè is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Otura Meji, Òtúrá Ogbè, Òtúrá Òyèkù, Òtúrá Iwòrì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òtúrá Ìrètè Odu.
