Ese — Yoruba Verse
Idin kulu
Oyekulu
Adifafun oya
Nijo ti komo re fosun
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo nibe orubo
Nje ero po ero ofa
Ewa ba ni ni jebutu ire gbogbo
BindinBidin
Idin iwori
Adia fun ohun monye
Omo ani kan tuledo
Igba ti n momi oju sogbere
Ebo ni won ni kose
Ogbebo ni be orubo
Iye olumon ye laye
Bindinbidin idin iwori
Iye olumonye laya
Bindinbin idin iwori
Iye olumonye nire gbogbo
Bindinbidin idin iwori
Idin osun
Idin owo
Adifafun orunmila
Nijo ti baba lolefe mosunlola
Omo won nipo asonulola
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo nibe orubo
Nje, iwo lofe mosun fun rare ole sun o lewo
Iwo lofe mosun funrare
Idin gaga gungun
Idin gigi roro
Adifafun ori nje
Ti n sunkun pe ohun oni enikan
Ebo ni won ni kose
Osi gbebo nibe orubo
Nje apa toni ohun oni borise
Kerekere won yio pada wato ori wa
Gbogbo ara ti won ni awon
Oni ba ori se kerekere
Won yio pada wato ori wa
Idin babanndin
Idin babandin
Adifafun alari tise eru iko
Igba ti be laarin ota
Ebo ni won ni kose
Ogbebo nibe orubo
Nje e wagba ese omo re
Ese alari oruko re o
E wa gbese omo re
Nje kakirin ebora losan
O adi irawo sasa loru
Idin ranhinranhin
Baba lawo oyin
Losefafun oyin
Igba ti momi oju sogbere ire gbogbo
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe orubo
Nje, ero po
Ero ofa
Ewa bani ni jebutu ire gbogbo
Gingo lago katogbo
Adifafun oluku ti gbogbo egbe re o mon la lata muti
Ebo ni won ni kose
Osi gbebo nibe orubo
Nje aluku gbo albino gbon
Aluku fagadayo areni tamufi mon
Idin sara
Idin soro
Adifafun toto beleje ti bakin sota
Ebo ni won ni ki ikin ose
Ikin gbebo nibe orubo
Nje ori abodi ogege mani o
Ori abodin
Idin kaka
Awo oba
Losefafun oba
Ojo ti oba suku pepa ohun okaye
Ebo ni won ni kose
Ogbebo nibe o rubo
Nje oba ni yio kadiwon
Ayamon boruko okawo
Oba ni yio kadiwon
Idin turu
Ipon turu
Adifafun kanbo
Ti lolegba obirin imu
Adifafun dindi tilo legba obinrin aya
Adifafun kuran ti lole gba obinrin idin
Ebo ni won ni kiwon o se
Won gbebo nibe won rubo
Nje kose ni ti o gba kanbo lowo imu
Koseni ti o gba dindi lowo aya
Koseni ti o gba kunran lowodi
Oti gbenu aho
Oti jawon logun
Goodagbo gbeju
Yolololo
Adifafun esinja
Abufu esikin
Igbati won momi oju sogbere ire gbogbo
Ebo ni won ni ki won o se
Esinkin ni kani beleyi tisebo
Iye eyin ori aje
Tofi ile esija le
Ile eni ti sikin lajelo
Ogun ni sinkin
Ogbon ni wora
Adifafun idin nijo tilole dileke nife
Ebo ni won ni kose
Ogbebo nibe orubo
Nje idin ni monti dileke
Ewo ore ti fase femi
Idin ni mon tidi ileke
Idin sese
Awo eja lo sefa fun eja
Nijo ti n gbogun lo ilodo
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Nje, ero ipo
Ero ofa
Ko si bi takan odo
Taa kan omo eja
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe ohun pe ire isegun fun eleyi pe ki eleyi orubo fun awon omo re tori isegun ki o si bori awon omo re pelu eye etu.
Ifa ni ohun pe ire gbogbo fun eleyi ki eleyi orubo ire gbogbo ki ole badi onire gbogbo ki o si lobo egungun pelu eran oruko kan, olele ebo obi.
Ifa pe ohun pe ire gbogbo fun eleyi ebo ni won ni kose ifa si ni ti eleyi ba fe fe obinrin ki o bere wo koto fe kole ba ni isinmi ki o si lobo ifa daradara.
Ifa sope ohun pe ire ifa fun eleyi ki eleyi ole bori faje ki olobo orire pelu opolopo igbin ki o si rubo fesu pelu akuko adire kan.
Ifa pe ohun pe ire isegun fun eleyi pe ki o lope se fun awon iyami aje pelu obe efo ati eran yinyan ki o si mon je eran yiyan lenu ojo meta yi.
Ifa pe ohun pe ire gbogbo fun eleyi ki eleyi o fi oyin kun ebo ru ki ire o le ba de fun.
Ifa pe ohun pe ire isegun fun eleyi ki eleyi orubo isegun ki o si lobo awon egbe re orun pelu opolopo oti.
Ifa so pe ohun pe ire isegun fun eleyi ki eleyi o lo fi ewure kan bo ifa tori kole basegun.
Ifa ni ki eleyi orubo ki pa re ole mon ka gbogbo ohun ti a ba fem on se kio fi oruka kun ebo ru.
Ifa ni ki eleyi orubo asegbe pe aya kan nibo kio fe kosi eni ti yio ye lowo ibewo ebo ni ko se.
Ifa sope ohun pe ire gbogbo fun eleyi ki eleyi orubo kio si mon ja kio si fi ade kan rubo ati eran oruko kan.
Ifa pe ire ola fun eleyi ki eleyi o lo fie ran ewure odidi bo ifa ki o mu die tutu ki o lo fi si ori ifa ki omu die ni tuutun kilo fi si ori ifa.
Ifa pe ire gbogbo fun eleyii, ki eleyii o si rubo ki okiki re o le baa kan si daa daa, ki o si fi eku, eja, abodie bofa.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu meji
Epo
Eko
Obi
Eran oruko meji
Olele
Eko
Obi
Oti
Epo
Eran oruko kan
Epo
Eko
Obi
Opolopo igbin
Akuko adire kan
Epo
Eko
Obi
Eran yiyan die
Opolopo efo
Epo
Eko
Obi
Akuko adire meji
Opolopo oyin
Epo
Eko
Obi
Akuko adie meta
Opolopo oti oyinbo
Ada kan
Epo
Eko
Obi
Ewure kan
Epo
Eko
Obi
Oti
Akuko adie meta
Oruka meji
Epo
Eko
Obi
Eran oruko kan
Akuko kan
Epo
Eko
Obi
Eran oruko kan
Ade kan
Epo
Eko
Obi
Eran ewure kan
Epo
Eko
Obi.
Eku kan
Eja kan
Abo adie kan
Epo
Eko
Obi