Ò
This Odu signifies the importance of adaptability and flexibility.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Owonrin sidi igongo
Idinwoi wolobe
Adifafun Orunmila
Igba ti be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, owo mi tesu apepe
Toba di amodun
N o sai bawon pe peregede
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni awon ota wa fun eleyii pe won si n wo o wioe ko ni di odun ti n bo, oe ebo ni ko ru.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Isu apepe
Eyele kan
Epo
Eko
Agado
Opolopo owo
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Yangi abori kugu
Adifafun Owon ti be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E wa bani larusegun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o boa won egbe, pe awon egbe re ni won yoo ba segun gbogbo ota ti o ni.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Gbogbo ohun tenu nje
Epa, ireke, aaadun, oyin
Ogede
Ekuru, eyin
Epo, eko
Agbado, owo
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Kalowi awo won lode ido
Ogangan laja awo owonrin sidi
Adifafun Orunmila
Ire gbogbo n lo lode okankan o yale
Ebo no won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, ifa boba je n laje
N o ma dupe lowo re edu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pere aje fun eleyii, ifa ni ebo ni ki eleyii o ru, ko si dimo oun ifa daa daa, pe oun ifa ni ki eleyii o dimo.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Akuko adire kan
Epo
Eko
Agbado
Owo
Obi meji
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Yangi abori kugu
Adifa fun Aje
Tii somo Olokun sanni Ade
Igba ti n fomi oju sogbere ire gbogbo
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E wa bani nin wowo ire
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pere ire aje fun eleyii, ifa ni ebo ni ki eleyii o se, ki o sib o orisa aje daa daa ki ire aje o le baa sunbo
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eyele meji
Epo
Eko
Agbado
Oti
Owo
Ekuru funfun
Obi
Explore Ifa
Òdì Òwónrìn is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Odi Meji, Òdì Ogbè, Òdì Òyèkù, Òdì Iwòrì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òdì Òwónrìn Odu.
