Ò
Òyèkù Òwónrìn Excerpt
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Oye wonrinmin
Oye sorinje
Oye sorinje paka paka sorinje
Adifafun onin waka waka
Toun aje jo n sota
Ebo ni won ni ki won o se
Onin waka waka ninkan ni n be leyin ti n be tubo
Ero ipo
Ero ofa
E bani larusegun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni eni kan ree ti ko jen kankan ofe, maa deru ba eleyii, pe ki eleyii o maa jeki eni toni nkan naa o nindi eru re.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Abe fele
Akuko adire kan
Epo pupa
Eko
Opolopo owo
Agbado
Aso eni yii toni awo winnin winnin
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Oye wonrinmin
Oye sorinje
Oye sorinje paka paka sorinje
Adifafun Ajibowu tii somo alagbede iwoye
Igba ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ki o se
Ajibowu nikan ni n be leyin ti n tubo
Ero ipo
Ero ofa
E bani bola peregede
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni kele o sora pe eni to sun mon eleyii kan lota re, ki o rubo pe yoo segun.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Abe fele
Akuko adire
Epo
Eko
Agbado
Opolopo owo
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Oye wonrinmin
Oye sorinje
Oye sorinje paka paka sorinje
Adifafun baba
Baba n sawo relu aje
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
Aje wa jede tururu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni eleyii n lo si ibi kan pe korubo pe yoo rire bo nibe.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu kan
Eyele kan
Epo igo kan
Eko meji
Agbado
Opolopo owo
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Yangi abori kugu
Adifafun oosa nla oseremagbo
Nijo baba n sunkun pe oun rire
Ebo ni won ni o se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, mo rire ninle
Morire loko
Ire to sonun
Ire wole de
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa loun pan eleyii korubo, pe yoo ri oore ninle re ati ni irin ajo lokere.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Opolopo igbin
Ekuru funfun
Epo
Eko
Opolopo owo
Explore Ifa
Òyèkù Òwónrìn is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Oyekú Méjì, Òyèkù Ogbè, Òyèkù Iwòrì, Òyèkù Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òyèkù Òwónrìn Odu.
