Ò
This Odu represents the need for caution and careful planning to avoid unforeseen dangers.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Oyeku teku asa
O yan kete kete
Adifafun popondo
Eni ti o gbori ote re dade
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E ba ni larusegun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo, pe aarin ota ni eleyii wa, sugbon aarin ota naa ni yoo ti la.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Akuko adire meji
Eyele meji
Abo adie meji
Epo
Eko
Agbado
Owo
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Oyeku teku asa oyan kete kete
Adifafun abe sekete ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, omode kii gboju gboju
Ko maa foribale fabe
Abe o maa ti dorisa
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni awon ota eleyii ju eleyii lo paa paa won ni agbara juu lo, pe ki eleyii o rubo gbogbo won ni n won o wa maa foribale bale fun un
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Abe fele meta
Akuko adire meta
Epo
Eko
Agbado
Opolopo owo
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Oyeku sale babe
Eruku so gbagba nin poro oko
Adifafun Erigi alo
Tii segbon ope agbe
Igba ti n fomi oju sogbere aje suru suru
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
Aje wa je de tuturu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ire aje n bo feleyii lati okere, oore naa sipo gidi gidi, pe ki eleyii o rubo koore naa o le too lowo
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu meji
Owo
Epo
Eko
Agbado
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Eminrin gesin bee ni koni kese
Amukuru gesin bee ni ko si bata
Ire toni kese toni bata beeni o rese gori esin
Adifafun Oyeku it n rele osa lee sawo
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, igba ti oyeku sawo dele osa
Eesin ni ao maa gun sawo
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ibi kan ni eleyii fee lo yii, pe korubo pe yoo ri ire aje mubo nibe
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Iyan ati obe egusi pelu eja
Oti
Obi
Abo adie meji
Epo
Eko
Agbado at owo
Explore Ifa
Òyèkù Ósà is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Oyekú Méjì, Òyèkù Ogbè, Òyèkù Iwòrì, Òyèkù Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òyèkù Ósà Odu.
