Ò
Òyèkù Ògundà Excerpt
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Atorinla abidi gbdagi
adifafun fojonda tii somo aja niwarun
Igba ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, ojo ti mo da eepe
Keni ma wule saloore
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo nitori pe laarin ota ni o wa, ki o le baa segun gbogbo won.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Akuko adire kan
Abo adie kan
Eyele kan
Epo pupa
Agbado
Owo
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Elegede ni n sawo inu igbo
Eremi ni n sawo awujaale
Adifafun folunlawe ti n je laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, owo te ewe segun sete temi
Ifa o to gege ki n maa segun ota mi
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo toripe aarin ota ni eleyii wa, pe ki eleyii o si se saara fun oku orun re ko le baa ni isegun.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Ewe segun sete ni isale igba ebo
Akuko adire meji
Epo pupa
Agbado
Owo
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Bebe o kehin
Bebe oke oun
Adifafun Orisa nla oseremagbo
Ti o n sunkun pe oun o foju
bare Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Morire nile
Mo rire lode
Ire to sonu, ire wole de
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni oore aje n bo lati okeere wa fun eleyii ati nibi ti eleyii ti n gbe pe o n saroye pe oun ko lowo lowo, pe ko rubo pe ire aje n bow a fun un.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Igbin merin
Eyele funfun meji
Epo
Eko
Obi merin
Agbado
Owo
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Oriri mori awo oba
Adifafun Oba
Ti n fomi oju sogbere aje sururu
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Ko e pe o
Ko e jinna
Aje wa jede tururu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa loju aje n pon eleyii pe ko rubo, ko si fi ogede ominin, eyin, ekuru funfun bo aje, aje yoo joko ti eleyii.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Opolopo eran ogede
Eyele meji
Opolopo oeo
Agbado
Explore Ifa
Òyèkù Ògundà is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Oyekú Méjì, Òyèkù Ogbè, Òyèkù Iwòrì, Òyèkù Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òyèkù Ògundà Odu.
