Ò
Òyèkù Iwòrì Excerpt
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Oyeku biwori tititi
Adifafun ike eyin amu
Igba ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E wa bani larusegun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo, awon ota kan n da eleyii laamu, won so pe eleyii o ni nisinmi
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Igba ademu kan
Akuko adie kan
Eyele kan
Epo igo kan
Eko meji
Opolopo owo
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Petenbole okirinkisi
Adifafun Olukoso laalu banbi arigbota segun
Igba ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Ki larira fi sete
Igba ota larira fi sete
Ki larira fi sete orubondu larira fi sete
Orubondu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo pe laarin ota ni o wa, ota lo yi eleyii ka, sugbon sango ni o ba eleyii segun, ki eleyii o fi okuta mesan kun ebo ru.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Amala gbegiri
Orogbo meji
Akuko adie kan
Oti
Opolopo owo
Eyele meji
Epo
Eko
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Oyeku biwori siyin
Oyeku biwori sohun
Owatanan ola saarin re
Singin singindin
Adifafun aje tii somo olokun osin eepe
Eyi ti o laa laa tenikan o nin le teni funman
Ebo ni won ni ko se
O sigbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
E wa bani bola peregede
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe ire aje fun eleyii, ifa ni owo naa yoo po debi wipe eni kan o ni maa bi owo re se poto mo
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Opolopo ekuru
Obi meji
Oyin
Oti
Eyele funfun kan
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Elegbe ni n kegbe awo ode aro
Ologba ni n kogba awo odofin
Oyeku loluwori lolugbonan
Boya oba seere maa itufu a si maa gbedire
Adifafun Orunmila
Ifa n sunkun ati la tururu
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
Aje wa jede tururu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa fore aje fun eleyii, ifa ni ebo ki re aje naa o le baa tete tee lowo ni ko ru
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Gbogbo ohun tenu n je
Akuko adie kan
Epo
Eko
Opolopo owo
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
Ao toju ori ologbo kan, odidi ataare kan, ewe eman, ewe awoyoyo, saworo pepe, ao jo papo, ao maa fi oti loo
Explore Ifa
Òyèkù Iwòrì is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Oyekú Méjì, Òyèkù Ogbè, Òyèkù Òdì, Òyèkù Íròsùn.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òyèkù Iwòrì Odu.
