I
Irete Meji in Ifa Divination emphasizes justice, balance, and the inevitability of cause and effect.
Listen
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Ateyin ayinte
Adifa fun Elede
Tiise yeye odo
Igbati mo mi oju sogbere omo
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo ni be orubo
Nje omo yoyo ni todo
Omo tosiwaju
Omo to seyin omo yoyo ni todo
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ohun pe ire omo fun eleyi pe oju omo n pon kio pa afiju ti kio le badi olomo laye kio si lo bo ifa pelu elede kan.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Odidi elede kan
Akuko adie kan
Epo
Eko
Obi
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Poro bayin
Ala bayin
Adifa fun ladebu
Tii se yeye oke
Igba ti momi oju sogbere aje
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni be orubo
Nje aje ile yii n ko o tokeni
Aya ile yii n ko o
Toke ni
Oke lotu wa
Toketoke leye etu ke
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ohun pe ire gbogbo fun eleyi pe ebo ni ko se pe ki eleyin osi mon bawon ja sinkan ogun tori ohun naa ni yio pada to si kio lobo orire pelu eye etu kan kio si fi eye etukan rubo.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu meji
Epo
Eko
Obi
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Ore oo
Ko re mi
Adifa fun ire
Ti lolete meji lodo
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni bne orubo
Nje igba irete meji
Ni ara ro awo.
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyi orubo pe ara ko ro eleyin fun ire gbogbo ki eleyi olote ifa ki ara ole baro
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eku meji
Eja meji
Abodie meji
Epo
Eko
Obi
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Ero yanuu fodo kete
Adifa fun atoka
Ti se ilari olodumare
Igba ti mo mi oju sogbere ire gbogbo
Ebo ni won ni kose
Ogbebo ni be orubo
Nje ilari oba oroko
Ilari oba orodo
Atoka wadi ilari
Olodumare.
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ohun pe ire gbogbo fun eleyi ki eleyi olodi mon ifa daradara pe eleda re ki ro ko ki yenaa ise ijoko ni eleda re mon se kio bo ifa pelu ewure.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eran ewure kan
Epo
Eko
Obi
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
Ao toju ewe ominni ao wa lopo mon iyere ao wa fi se igbin merin lepo ni yo ao wa se adura si eni naa yio je obeyin.
ISEGUN
ESE AKOSE KEJI
Ao toju ori igbin ao toju ewe apada ati atare kan o wa jo po ti obajo tan ao wa fi sigbere igba ati eyokan si aarin ori, ao fi iyokun fokomu lekan soso lori odo.
Explore Ifa
Irete Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Ìrètè Ogbè, Ìrètè Òyèkù, Ìrètè Iwòrì, Ìrètè Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Irete Meji Odu.
