Í
This Odu highlights the need for patience and perseverance in achieving success.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Ifa ni ika ni ika
Eleja irete ni
Irete elewo adifafun iku mon payi
Ti n se omo bibi inu agbon niregun
Igbati ntorun bow a saye
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe orubo
Nje ki iku mon payi
Ojo gbo ko jato
Kolero leyin pitipiti
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ki eleyi orubo lori omo re kan to je abiku ki o mon je pe yio ku danu lasan kole diru ko le digba
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Oruko kan lebo
Ewure kan
Akuko adie meji
Epo
Eko
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Ifa ni ikanika
Eleja irete ni
Irete elewo
Adifafun orunmila
Oke ipori Baba ogba
Ewo nitori ajogun gbogbo
Nje ifa rowa ko wa jewo
Nitori ajogun gbogbo
Oba tete row a
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe ki eleyi o fi ewo bo Ifare nitori ajogun buruku ki eleyi o mon fi ebo se alo
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Opolopo ewo
Eku
Eja
Akuko adie meji
Epo
Eko
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Ifa ni baba gbede ila
Baba gbede ikan
Adifafun ika tin lo le te irete
Nitori ire gbogbo
Ebo ni won ni ko mon se
O si gbebo nbe orubo
Nje ika wo ni
Ika to te irete
Nitori ire gbogbo
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe ki eleyi o lo te ifa la gbogbo nkan tole ninu aye re o le ba di ero pese ifa pe omo iya eleyi niyo sodi eni ola laye re
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu meji
Eyele meji
Akuko adie meji
Epo ati eko
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Ifa ni karete karete
Adifafun orunmila
Nijo ti ori baba ogbo
Ebo ni won ni kose
O si gbebo nibe orubo
Nje mo ti magbon bori mi
Ori mi mon mon gbo
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ki eleyi o ba ori re nitori gbogbo nkan ti eleyi nse k obo si ojuto ki o si lo bo Ifa re dada
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Agbon
Obi
Oti
Eyele funfun meta
Pepeye meji
Epo
Eko
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
ISEGUN
Ori eku olose ori eja ajabo ori eyekeye Ikamundun meje tabi mesan ataare a o lo papo a o te ni odu Ifa ika eleja a o sure isegun si dada ao fi sin gbere si aarin ori lati iwaju de ipako ao po iyoku mon ose dudu ao fi we ni ojo keta ti ati sin gbere na.
Explore Ifa
Íká Ìrètè is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Ika Meji, Íká Ogbè, Íká Òyèkù, Íká Iwòrì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Íká Ìrètè Odu.
