Ò
Òyèkù Óbárà Excerpt
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Oyeku faba goke baba lawo oluweri
Adifafun oluweri
Igba ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Nje, enikan kii ba omi sote
Enikan kii ba omi sota
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni laarin ota ni eleyii wa sugbon yoo rubo kole baa ni isegun jale tan lowo awon ota re.
Ifa ni ore kan niyi ti oun ati eleyii jo n rin, ifa ni kee sore re, ko si mo maa so oro re fun un mo.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Abo adie
Akuko adie
Eyele
Epo pupa
Agbado
Opolopo owo
Eye etu
Opolopo owo
Epo pupa
Eko
Agbado
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Agbori odidifa agbaja sapele
Adifafun eeman ajala
Ti o nire gbogbo juwon lo
Ebo ni won ni ko se
O si rubo
Ero ipo
Ero ofa
E wa bani bola perengede
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni kele yii o rubo pe yoo ni owo lowo ju awon eeyan re yoku lo.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Akuko adie kan
Eyele meji
Epo pupa
Eko
Agbado
Opolopo owo
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Oyeku palaba ipabo sagodogba
Eluju eluju isagodo gba ipara
Adifafun Orunmila
Ire gbogbo nlo nita
Okankan o ya le wa
Ebo ni won ni kifa o se
O si rubo nibe
Ero ipo
Ero ofa
Aje wa jede tuturu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe ire lati okere fun eleyii pe ebo ni ki eleyiii o ru pe yoo nire gbogbo
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Abo adie kan
Eku meji
Eja meji
Eye etu
Epo pupa
Eko
Owo
Agbado
Explore Ifa
Òyèkù Óbárà is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Oyekú Méjì, Òyèkù Ogbè, Òyèkù Iwòrì, Òyèkù Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òyèkù Óbárà Odu.
