Ò
This Odu highlights the importance of adaptability and flexibility in the face of challenges.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Jekere jekere awo ika
Adifafun ika
Jekisi jekisi awo oye
Adifafun Oye
Adifafun Oyeke oun ika
Igba ti won sawo rebi atoke doke
Ebo ni won ni ki won o se
Ika nikan ni n be leyin ti n tubo
Oyeku bika oloun bika
Asareyin letan je baun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni eleyii ati enikan jo n sowo, pe eni naa yoo daa tabi oun ni yoo fed a enikeji re, sugbon ebo ni ko ru pe oore ni yoo ja si fun un.
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Opolopo agbado
Eyele meji
Abo adie kan
Epo
Eko
Agbado
owo
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Oyeku bika oloun o bika
Adifafun Morogbejo
Tii sare man olodumare
Igba ti n be laarin ota
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje, Oyeku bika
Oloun bika asarayin letan je baun
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo fun omo re pea won ota n se omo re nika, sugbon ori omo re yii ni yoo ba segun
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Aso funfun
Aso dudu
Aso ayinrin
Eyele kan
Abodie kan
Epo
Eko
Owo
Agbado
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Oyeku bika bika
Adifa fun omo olokun osin eepe
Igba ti n tode orun bowale aye
Ebo ni won ni ko se
O sigbebo nibe o rubo
Ero ipo
Ero ofa
Aje wa jede tururu
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni ki eleyii o rubo senu ise re pe ire aje n bo fun eleyii nibe .
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Eye etu kan
Obi meji
Oti
Eyele kan
Epo
Eko
Agbado
Opolopo owo
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Yangi abori kugu
Adifafun Aje
Oun omo jo n jija agba nile Olodumare
Ebo ni won ni ki won o se
Aje nikan ni n be leyin ti n tubo
Ero ipo
Ero ofa
E wa bani bola peregede
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa ni laarin awon omo iya eleyii pe oun ni yoo la ju gbogbo won lo sugbon ebo ni ko ru
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Wara eyin ogede
Ekuru funfun
Obi meji
Owo
Epo pupa
Eko
Agbado
Explore Ifa
Òyèkù Íká is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Oyekú Méjì, Òyèkù Ogbè, Òyèkù Iwòrì, Òyèkù Òdì.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Òyèkù Íká Odu.
