O
This Odu signifies the power of transformation and the importance of embracing change.
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ese — Yoruba Verse
Ogunda batubatu mojalawa
Adifafun fun eerinle
Ti n momi oju sogbere aya
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pere fun eni toda ifa yi ifani oun pere aya fun eleyii korubo ki ire aya ole ba to lowo
Ebo — Sacrifice (Yoruba)
Agbeboadie
Eku
Eja
Opolopo owo
2
Ese Keji
Ese Keji
Ese — Yoruba Verse
Ewe igba ni o taka sudi
Ewe emi ni n lura won pelenge pelenge
Adifafun soto omo oba tutu
Igba ti n momi oju sogbee ire
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pere fun eni toda fayi ifani oun to toripe dafasi ifa ni orire ni kodi mun kobo orire dada ki ire ole bade fun
Ifa pere omo fun eleyi ifa ni oun ati awon kanjo ndun inkan ifa ni ko rubo ko le ja mo lowo ko si rubo ni tori omo ifa ni oju omo n pon ifa komo se aigboran
Ifa pere fun eni to da ifa yi ifa ni enu nkuneleyii won nsope koni damodun ifani eleyi o sun orun korun osi lala kala korube to ri iku
Ifa pere fun eni toda ifayi ifa ni oju omo ni pon eleyi ko rubo ko le babimo
Ifa pere fun eni to da ifayi ifa oju ire gbogbo ni pon eleyi korubo ko si lo fi opolopo owa eyan ba ogun
3
Ese Keta
Ese Keta
Ese — Yoruba Verse
Wawa olugun ni won n fi sun kun
Koobo esin ni o se ko fesin
Adifafun ire
Ti n lo lee joba nidi igba
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pe oun pere ola fun oun si pere oye ifa ni won ma jo ye nidi le awon eleyii ifa pe yo si raye se ifa pe olomisin eyan ni ko rubo
Ifa pere fun eni to da ifa yi ko rubo ifa ni ko ni isimi ifami eleyi o un damun pe korun ki idamunre ko le do pin ifa ni koni inkankan ko rubo kole ba ni re gbogbo
Ifa pere fun eni toda ifayi ifani keleyi orubo nitori arun ko si mo gbekeleagbara ifa ni ko mo ba eniyan ja ifa [pere aya ifa ni awon merin jo nja si inkan kan ifa pe ki eleyii o rubo ko le ba bosi lowo ona meta ni won orubo yi si
Ifa pere fun eni to da ifayi ifa ni oju aje pon eleyi ifa ni eleyii fe lo ibikan lowa bere si ifa ni korubo ko to lo ki o le ba ko ire bo ni be
Ifa pere fun eni to da ifayi ifa ki eleyii o rubo ki ajinde ara ko le ba mAJE ti eleyii ifa ni oun pe re aiku fun eleyi.
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ese — Yoruba Verse
Ona totaramoya
Adifafun ogun
Ti n lo igboje eluju je
Ti n lo lee foba wasinu ile
✦
Ase — Ifa Spiritual Message (Yoruba)
Ifa pere oun pere aya fun eni toda ifayi tobaje pe okunrin ni toba sijepe obinrin ni ifa pere ibujoko fun ko rubo
Ifa pere fun eni toda ifa yi ifa ni arin ota leleyi wa ifa ni korubo ko le ba bolowo won kofi ewa sise ati okuta were pese
Ifa pere fun eni toda ifayi ifa ni korubo nitori iku ifa si ni enikan o fi oro kan si eleyii lowo komo sofun enikan kan kosibo oriiyare ki ori iyare o leba koyo nu ewu
Ifa pere fun eni toda ifayi ifa ni oju omoni pon eleyi ifa ni otida mun damun korubo ki idamunre o le jasi ayo
Ifa pere fun eni to da ifayi ifa ini kieleyi o rubo ija ogun ko si bo ogundada
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
Ewe ire pupo ede pupa pupo ewe akoko aojopo ao ro sinu sere ao pa akuko kan aoro eje si ara sere yi ao ma fi fo eko tutut mun laro laro
Ewe akisan, ewe ire, ewe aje ewe oju oro ewe osibata omo migedegede funfun ao ko gbogbo inkan inu aboadie pomo ao gunwon papo mo ose ao ko sinu igba olomori ao ma fiwe laro laro.
Eyele kan igbin kan ewe rinrin ewe olonjongbodu ao jo op ao ma fi fo eko tutu mun larolaro.
Ewe iyun eye ao lo ao fi se eja ojiji meta eja aro meta lepo niyo ti o ba tiji nan ao kaje
Ewe oruru tutut aogun papo mo iya AJE nlakan ati awo igala ao wa gunpo mo ose ao ko sinu igba olomori ao pa akuko kan aore eje re si ose ao po mo ao wa fi ori adie yi te igba ka to ko ose si ao mo fiwe laro laro.
Isegun / Akose — Victory Formula
Yoruba
Egbo igba irula asesin adie ao gun po mo ose ao mo fi we laro laro
Imi orun ao lo pomo etu ibon igidi ao fi singbere meta si arin ori.
Iginla die eso oloweremjeje meta eyo atare meta ao lo po mo arawon ao fi singbere eji ogbe si apa mejeji
Kuku agbado odun tolo egbo akere jupon ao jopo mo ara won ao wa po mo ose ao ma fiwe ori ni kan
Afomo igba a fomo ewe lapo lapa funfun igba adie ori aparo kan aojopo mo arawon ao fi singbere yi po orun owo mejeeji.
Explore Ifa
Ogunda Oturupon is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that forms the foundation of the BODE Oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Akose (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Ogunda Meji, Ogunda Ogbe, Ogunda Oyeku, Ogunda Iwori.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Ogunda Oturupon Odu.
